Ijebu

Nigeria

Network partner Yinka Shonibare Foundation, a charity dedicated to facilitating international cultural exchange, builds their conceptual weather station The Farm, focusing on the impact of weather on local knowledge, tradition and practice concerning farming and weather patterns.

Ijebu

Nàìjíríà

Alabaṣepọ Nẹtiwọọki Yinka Shonibare Foundation, ifẹ ti a ṣe igbẹhin si irọrun paṣipaarọ aṣa agbaye, kọ ibudo oju-ojo ero wọn The Farm, ni idojukọ lori ipa oju-ọjọ lori imọ agbegbe, aṣa ati iṣe nipa ogbin ati awọn ilana oju ojo.

About this weather station

THE FARM

The Farm is a conceptual weather station in the village of Ikiṣẹ near the town of Ijebu Ode in Ogun State, Nigeria. It sits on the 54-acre working Ecology Green Farm that lies just two hours from Lagos. The expansive and lush land hosts Guest Artists Space (G.A.S.) Foundation in a purpose-built residency building, providing practice and research space for those working across a variety of disciplines including craft, design, art, the environment, food sustainability and agriculture. The Farm delivers a contrasting experience to our second residency location in Lagos where a brutalist-inspired building informed by traditional Yoruba architectural principles, is situated on the reclaimed island area of Oniru in the largest and most populous city in Africa.

The Ecology Green (EG) Farm was founded by the Nigerian-British artist Yinka Shonibare in 2018. Built on ecological principles and sustainable approaches to circular farming which provide the backdrop and context for this innovative and unique residency space. The G.A.S. building, known as the Farm House, was constructed from 40,000 earth bricks, handmade from the soil and is surrounded by abundant vegetation that accommodates ten greenhouses (some aquaponic), fish ponds, chickens, cows and geese. Crops including tomatoes, peppers, cassava and cashews populate expansive fields that also sustain the replanting of rainforest areas.

Nigeria has a largely tropical climate, with variable wet and dry seasons that can experience, sometimes extreme, fluctuations across a wide range of conditions, rainfall levels and temperatures. The country is home to a diverse and varied ecological makeup of mangrove and freshwater swamps along the coast, a rainforest belt and savannah and semi-desert conditions further north as a result of the alarmingly southward advance of the Sahara.

Raqs Media Collective (Jeebesh Bagchi, b.1965, New Delhi, Monica Narula, b. 1969, New Delhi, Shuddhabrata Sengupta, b. 1968, New Delhi) will be the G.A.S. residents and weather reporters on the Farm as part of the World Weather Network. Variously described as artists, media practitioners, curators, researchers, editors and catalysts of cultural processes, their work is located at the intersections of contemporary art, historical enquiry, philosophical speculation, research and theory, often taking the form of installations, online and offline media objects, performances and encounters.

Raqs Media Collective will explore the weather station from an experiential, conceptual and human-based approach, collecting and recording weather reports visually and through oral narrative experience, supported by real-time weather data from open sources.  Key areas of focus may include the impact of weather on local knowledge, tradition and practice in relation to farming and weather patterns, the loss of vegetation, forests and farmland and food sustainability, as well as the tracing of the connections that weave all these together.

They will work with other G.A.S. residents, visiting artists and researchers across these themes, whilst engaging with a wider network of peers, artists, scientists and farmers across the very different geological regions of Nigeria.

YINKA SHONIBARE FOUNDATION

The Yinka Shonibare Foundation (Y.S.F.) was established in 2019 by the eminent British-Nigerian Artist Yinka Shonibare CBE RA, whose international multi-disciplinary practice explores colonialism and post-colonialism within the context of globalisation. The Yinka Shonibare Foundation is a UK registered charity (charity no 1183321) dedicated to facilitating international cultural exchange and supporting creative practices through residencies, collaborations and education projects.

Shonibare’s vision behind the Foundation is to support the development of new work and ideas, to foster mutual understanding of cultural differences as we break down traditional barriers of privilege and wealth, to build access and create new pathways to education, to forge new networks and a resilient cultural infrastructure that will enable the next generation to thrive, not just survive.

The Foundation's vision is implemented through hosting and supporting residencies, education and professional development programmes in the UK and Nigeria. In Nigeria, partnering with its sister organisation Guest Artists Space Foundation a registered non-profit, the Foundation will provides multi-use live/work residency spaces in the heart of the dynamic city of Lagos and on a rural working farm in Ijebu, Ogun State.

Nipa ibudo oju ojo yii

THE FARM

Oko yìí jẹ́ ibùdó tí a ti ṣẹ̀dá ojú-ọjọ́ tó wà ní abúlé Ìkiṣẹ̀ nítòsí Ìjẹ̀bú-Òde, Ìpínlẹ̀ Ògùn, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó fìdí kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ eékà mẹ́rìnléláàádọ́ta níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ nípa  Ìbáṣepọ̀-ẹ̀dá-àti-agbègbè-rẹ̀ lÓko, ní ibùdó tí kò ju ìrìn wákàtí méjì lọ sí ìlú Ekó). Ilẹ̀ ọlọ́ràá tó gbòòrò yìí ni ó gba Guest Artists Space (G.A.S) Foundation lálejò níbi tí a kọ́ ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú gbogbonìṣe sí, nínú ilé yìí ni wọ́n ti ń ṣe àgbéjáde iṣẹ́ ìwádìí fún àwọn tí wọ́n ń ṣe  onírúurú iṣẹ́ bíi iṣẹ́-ọwọ́, ìyàwòrán, iṣẹ́-ọnà, iṣẹ́ àwùjọ, ìpèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, àti iṣẹ́ àgbẹ̀. Oko yìí ni a ti ń rí ìrírí tó yàtọ̀ sí ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú èkejì tí a gbé kalẹ̀ sí ìlú Èkó níbi tí a tí rí ilé aláràm̀barà tí a kọ́ pẹ̀lú ìlànà ilé-kíkọ́ láwùjọ Yorùbá. Ó wà ní erékùsù Onírù ní ìlú tó tóbi jù, tó sì gbajúmọ̀ jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀. Ètò Ìbáṣepọ̀-ẹ̀dá-àti-agbègbè-rẹ̀ lÓko ni a dá sílẹ̀ lọ́dún 2018 láti ọwọ́ Yínká Shónibárẹ́ tí wọ́n jẹ́ oníṣẹ́-ọnà ọmọ bíbí ilẹ̀ Nàìjíríà àti ilẹ̀ Bìrìtìkó.

A gbé e kalẹ̀ lórí àpapọ̀ ìlànà Ìbáṣepọ̀-ẹ̀dá-àti-agbègbè-rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀nà mímú ìdàgbàsókè bá iṣẹ́ àgbẹ̀, èyí ni yóò pèsè àtìlẹyìn ọ̀tun fún ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú yìí. A kọ́ Ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú ti G.A.S., tí a mọ̀ sí Ilé-oko pẹ̀lú búlọ́ọ̀kù amọ̀ ọ̀kẹ́ méjì, tí a mọ láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀. Ọ̀pọ̀ ohun-ọ̀gbìn ni ó yí i ká, tí ó sì fààyè gba ilé-oko mẹ́wàá (tó fi mọ́ ilé-ọ̀sìn ẹja), odò ẹja, àti ohun-ọ̀sìn bíi adìyẹ, màlúù àti abo pẹ́pẹ́yẹ. Ohun-ọ̀gbìn bíi tòmátì, ata, ẹ̀gẹ́, àti kajú ni ó gbilẹ̀ nínú ọgbà yìí, tí ó sì fààyè gba àtúngbìn ohun-ọ̀gbìn nínú oko ẹgàn. 

Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè tó wà ní agbègbè tí ojú-ọjọ́ rẹ̀ gbóná, pẹ̀lú onírúurú àyípadà bíi ìgbà òjò àti ìgbá ẹ̀ẹ̀rùn, nígbà mìíràn àwọn ìgbà ojú-ọjọ́ yìí lè pàpọ̀jù, wọ́n sì lè ṣe ségesège nígbà òmíì. Èyí máa ń wáyé látàri onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ bíi, ìdiwọ̀n òjò àti ìgbóná ojú-ọjọ́. Orílẹ̀-èdè yìí ní onírúurú ewéko pẹ̀lú ibùdó wọn ní àwọn agbègbè omi tó mọ́ geere ní ipadò, oko ẹgàn, ilẹ̀ ọ̀dàn, àti àwọn ilẹ̀ tó fapá kan jẹ́ aṣálẹ̀ ní apá aríwá látàri sísúnmọ́ tí Aṣálẹ̀ súnmọ́ wa ní apá ìhà gúsù.

Raqs Media Collective (Jeebesh Bagchi, b.1965, New Delhi, Monica Narula, b. 1969, New Delhi, Shuddhabrata Sengupta, b. 1968, New Delhi) yóò jẹ́ oníròyìn fún G.A.S. lórí èto ibùdó-ìkọ́ni-aráàlú àti akàròyìn ojú-ọjọ́ nínú Oko yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ilé-iṣẹ́ Akàròyìn Ojú-ọjọ́ lÁgbàáyé. A ó máa pè wọ́n ní onírúurú orúkọ bíi oníṣẹ́-ọnà, oníṣẹ́ ìròyìn, adarí ètò, olùṣèwádìí, olótùú àti agbáṣàga. Iṣẹ́ wọn wà ní ìkóríta àwọn iṣẹ́-ọnà tòde-òní, ìṣèwádìí ìtàn, àsọtẹ́lẹ̀ nípa àròjinlẹ̀, tíọ́rì àti iṣẹ́-ìwádìí. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń wà ní ìbámu pẹ̀lú àtòpọ̀ ètò ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ẹ̀rọ akàròyìn lórí ẹ̀rọ ayélujára àti tojú ayé, ìṣe àti ìbápàdé.

Raqs Media Collective yóò ṣe àyẹ̀wò ibùdó ojú-ọjọ́ yìí nípa ṣíṣe àmúlò ìlànà ìrírí, ìlànà àforírò àti ìrònú-ẹ̀dá, gbígbà àti kíká àwọn ìròyìn nípa ojú-ọjọ́ sílẹ̀ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lójúkojú àti gbígba àlàyé nípa àwọn èyí tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, pẹ̀lú ìtọ́kasí láti ara ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-ọjọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn ìtọ́kasí tó wà lóde. Àwọn àkórí tó ṣe pàtàkì tí a fẹ́ jíròrò lé lórí leè jẹ́ ipa tí ojú-ọjọ́ ń kó lórí ìmọ̀ ilẹ̀ wa, àṣà àti ìṣe tó jẹmọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti bátánì ojú-ọjọ́, pípàdánù àwọn ohun-ọ̀gbìn, igbó àti oko pẹ̀lú ìṣètọ́jú oúnjẹ, àti ìṣàwárí àwọn ọ̀nà mìíràn tó lè ṣe àkópọ̀ àwọn àtòjọ òkè yìí.

Wọn yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ G.A.S., àwọn oníṣẹ́-ọnà tí a gbà lálejò àti àwọn olùṣèwádìí lórí àwọn àkórí yìí, bí a ti ṣe ń jíròrò pẹ̀lú àwọn tí ọjọ́-orí wọn jẹ́ bákan náà, oníṣẹ́-ọnà, onímọ̀ sáyẹ́ńsì àti àwọn àgbẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Nàìjíríà.

YINKA SHONIBARE FOUNDATION

A dá àjọ Yínká Shónibárẹ́ Foundation (YSF) sílẹ̀ ní ọdún 2019 láti ọwọ́ ẹni-ọ̀wọ̀ oníṣẹ́-ọnà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ-bíbí ilẹ̀ Nàìjíríà àti ilẹ̀ Bìrìtìkó, Yínká Shónibárẹ́ CBE RA, ẹni tí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ wọn dá lórí ìjọba-ìmúnisìn àti ìmúnisìn lẹ́yìn òmìnira ní àgbáyé. Àjọ Yínká Shónibárẹ́ Foundation jẹ́ àjọ onínúure tí a ṣe ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀ lórílẹ̀-èdè UK, pẹ̀lú èròǹgbà láti ṣe agbátẹrù ìṣepàsípààrọ̀ àṣà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lágbàáyé àti láti máa ṣe àtìlẹyìn fún àwọn oníṣẹ́-ọnà nípa ṣíṣètò àwọn àkànṣe iṣẹ́ lórí ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ètò-ẹ̀kọ́.

Ìran Yínká fọ́jọ́-iwájú Àjọ yìí ni láti máa ṣe àtìlẹyìn fún iṣẹ́ àti èrò tuntun lọ́nà láti mú kí àgbọ́yé wà láàárín onírúurú àṣà, èyí yóò mú wa ṣẹ́gun ìdènà ọjọ́ pípẹ́ láti ṣí àwọn ọ̀nà tuntun sílẹ̀ fún ọrọ̀, ìdàgbàsókè ètò-ẹ̀kọ́, mímú ìgbà ọ̀tun bá ètò ìmọ́ra-ẹni àti kíkọ́ ilé tó dúró déédé ní ìbámu pẹ̀lú àṣà wa, èyí yóò mú ìdàgbàsókè bá ìran tó ń bọ̀, kì í ṣe kí wọ́n kàn wà láyé lásán.

A ó mú Ìran ọjọ́-iwájú Àjọ yìí ṣẹ nípa ṣíṣe àtìlẹyìn àti ètò ibùdó-ìkọ́ni-fáráàlú, ṣíṣe ètò-ẹ̀kọ́, pẹ̀lú ṣíṣètò fún ìdàgbàsókè àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti UK. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, níní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Àjọ Guest Artists Space Foundation, tí a ṣe ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Àjọ onínúure, Àjọ yìí yóò pèsè ààyè ńlá fún ìlo-gbogbonìṣe fétò ibùgbé àti iṣẹ́ fáwọn olùgbé ìlú Èkó àti oko ní ìgbèríko ìlú Ìjẹ̀bú, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.

Weather Reports

Fluffy Blue Cloud Icon

The Rain in Lagos

Adéwálé Májà-Pearce

26 August 2022

Partners

black text on transparent background

Related